Psalms 97

1Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀
jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn
2Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká
òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
3Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri
4Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé
ayé rí i ó sì wárìrì
5Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,
níwájú Olúwa gbogbo ayé.
6Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

7 aGbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,
àwọn tí ń fi ère gbéraga,
ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

8Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn
inú àwọn ilé Juda sì dùn
Nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa
9Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ
ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
10Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́
Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́
ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo
àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn
12Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,
kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Copyright information for YorBMYO